jueves, 7 de marzo de 2019

EL RESULTADO DE LA DESOBEDIENCIA Y LA CODICIA

EL RESULTADO DE LA DESOBEDIENCIA Y LA CODICIA
THE RESULT OF DISOBEDIENCE AND GREED
ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ
Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Ìjàpá/Àjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí. Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn. Yáníbo ko dúró lásán, ó tọ Babaláwo lọ láti ṣe ãjo bí òhun ti le ri ọmọ bí.
Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo. Babaláwo kìlọ̀ fún Ìjàpá gidigidi wípé õgùn yí, obìnrin nìkan ló wà fún, pé kí o maṣe tọwò. Ìjàpá ọkọ Yáníbo ṣe àìgbọràn, ó gbọ õrùn àsèjẹ, ó tanwò, ó ri wípé ó dùn, nítorí ìwà wobiliki ọkánjúwà, o ba jẹ àsèj̀ẹ tí Babaláwo ṣe ìkìlọ̀ kí ó majẹ. Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú. Yorùbá ni “ohun ti a ni ki Baba mágbọ, Baba ni yio parí rẹ”. Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ:
CANCION
Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀, Alugbirinrin 2ce
Õgùn to ṣe fún mi lẹ́rẹkan, Alugbinrin
Tóní nma ma fọwọ́ kẹnu, Alugbinrin
Tóní nma ma fẹsẹ kẹnu, Alugbinrin
Mo fọwọ kan ọbẹ̀, mo mú kẹnu, Alugbinrin
Mofẹsẹ kan lẹ mo mu kẹnu, Alugbinrin
Mobojú wo kùn o ri gbẹndu, Alugbinrin
Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀, Alugbinrin 2ce
Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀. Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú.
Ìtàn yí kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú. Ìtàn Yorùbá yi wúlò lati ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ti o nwa owó òjijì nípa gbígbé õgùn olóró mì lati kọjá lọ si òkè okun/Ìlúòyìnbó lai bìkítà pé, bí egbògi olóró yí ba bẹ́ si inú lai tètè jẹ́wọ́, ikú ló ma nfa. Ìtàn nã bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí.
ENGLISH
A long time ago, child birth played an even greater role in Yoruba society and women unable to give birth to a child went through great lengths to conceive. Frantic efforts by all the women to have babies was exemplified by Yanibo, the Tortoise’ wife. Yanibo was no exception at her time, so she went to seek fertility treatment from the Herbalist.
The Herbalist prepared a fertility treatment meal for Yanibo, who sent her husband to collect the meal on her behalf. The Herbalist warned Tortoise strongly not to taste the meal as it was strictly for women. Tortoise smelt the meal on his way home and was thereby tempted as a result of the sweet aroma, he therefore, ate the fertility meal.
On getting home he had to cover up with lies as if the fertility meal was not ready, but in a short while, his stomach began to swell. And so goes the Yoruba saying, “what is hidden from one’s father will eventually be settled by him”. The result of Tortoise disobedience and greed made him suffer unbearable pain, hence he summoned up his last energy and began to sing to attract pity on his way to the Herbalist’s place. Yoruba pleading song: “Babalawo mo wa bebe…”
By the time Tortoise got to the Herbalist, it was too late as the Herbalist had told him earlier that there was no antidote, so the Tortoise died.

This story is used to warn against the grave consequences of greed, disobedience, lying and other vices. It can also be used to warn people who engage in corrupt means to getting rich such as those swallowing wraps of hard drugs, without minding that it might lead to death if such wraps burst in the stomach. The story also serves as a warning to those lying, disobedient and those robbing either individual or government.

´´ Español ´´
Hace mucho tiempo, el nacimiento del niño jugó un papel aún mayor en la sociedad yoruba y las mujeres que no podían dar a luz tuvieron un gran esfuerzo para concebir. Yanibo, la esposa de la tortuga, ejemplificó los frenéticos esfuerzos de todas las mujeres para tener bebés. Yanibo no fue la excepción en su momento, así que fue a buscar un tratamiento de fertilidad al Babalawo.
El Babalawo preparó una comida de tratamiento de fertilidad para Yanibo, quien envió a su esposo a recoger la comida en su nombre. El babalawo advirtió a Tortuga que no probara la comida ya que era estrictamente para mujeres. La tortuga olió la comida en su camino a casa y se sintió tentada como resultado del dulce aroma, por lo tanto, comió la comida de fertilidad.
Al llegar a casa tuvo que cubrirse con mentiras como si la comida de fertilidad no estuviera lista, pero al poco tiempo su estómago comenzó a hincharse. Y así es como dice el yoruba, "lo que está oculto para el padre de uno será resuelto por él". El resultado de la desobediencia y la codicia de la tortuga lo hicieron sufrir un dolor insoportable, por lo que reunió su última energía y comenzó a cantar para atraer la compasión en su camino hacia el lugar del herbolario. Canción suplicante yoruba: "Babalawo mo wa bebe ..."
Cuando la Tortuga llegó al Herbolario, ya era demasiado tarde, ya que el Babalawo le había dicho antes que no había un antídoto, por lo que la Tortuga murió.
Esta historia se utiliza para advertir contra las graves consecuencias de la codicia, la desobediencia, la mentira y otros vicios. También se puede usar para advertir a las personas que se involucran en medios corruptos para que se hagan ricos, como los que ingieren envoltorios de drogas duras, sin tener en cuenta que podría causar la muerte si tales envoltorios revientan el estómago. La historia también sirve como una advertencia para aquellos que mienten, desobedientes y que roban a individuos o al gobierno.

No hay comentarios:

Publicar un comentario